Oludije si ipo gomina ni ipinle Osun labe asia egbe African Action Congress (AAC), Ogbeni Olufemi Johnson ti gbogbo eyan mo si sogbadero lo fi ye gbogbo omo Osun wipe Ipinle Osun kun fun wara pelu oyin ati ohun a mu soro to le je ki gbogbo omo ipinle Osun o gbe igbe aye irorun sugbon o se ni laanu wipe awon odaju oloselu lo n dari ohun alumoni wa yi. o so eleyi ni bi eto ti Sogbadero political movement pelu egbe AAC ipinle Osun gbe kaale lati ta awon omo ipinle Osun ji nipa eto oro Oselu ati idije sipo gomina eyi to n bo lona. Ogbeni Olufemi Sogbadero ni ti awon eyan ipinle Osun ba le fi ibo won gbe ohun wole gege bi gomina ipinle Osun, o ni ohun se tan lati mu aye derun fun gbogbo omo ati olugbe ipinle Osun. O ni asiko ni yi lati dibo yan odo to kaju e lati dari eto isejoba ipinle Osun fun ilosiwaju ninu eto eko, eto iwosan to peye, eto oro aje to muna doko, eto a mu aye derun loju popo ati reluwe, gbigbe asa ati ise wa laruge pelu mi mu ojuto awon agbegbe igbafe ati awon ibi ti awon