Bi gbogbo eyin omo ipinle Osun se n jade lati lo dibo yan oludari tuntun loni, mo ro yin lati yago fun tita ibo yin. Asiko ni yi fun yin lati tun so bi odun merin yin miran tun se ma ri. Oro yi lo jade lenu oludibo si ipo gomina ipinle Osun labe asia egbe African Action Congress AAC Ogbeni Olufemi Eniolapo Johnson. Ninu oro re, o ni awon ti gbaradi fun ohun gbogbo to lewu ko sele loni ninu eto idibo na. O ni bi egbe oselu kankan ba gbiyanju lati ra ibo abi wu iwa ko to kankan loni, awon yo si won lona ti won ko lero rara tori awon o ni laju kale ki won o tun je awon omo ipinle yi mo aye fun odun merin miran. O ni ki onile o gbo, ko so fun toko, ko ni si aye magomago kankan loni tori wipe awon na ti mura won sile. O ni awon o ni ra ibo be si ni awon omo egbe awon o ni ta ibo won fun enikeni. Ipinle Osun, ti gbogbo wa ni tori eyi a gbodo dibo bo ti to ati bo ti ye.