Osun 2022, Ko si ohùn tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun - ọmọ ọba Adeola Adeyeye.
Osun 2022, Ko si ohùn tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun - ọmọ ọba Adeola Adeyeye.
Ọmọ Ọba Hafeez Adeola Adeyeye to je alukoro ẹgbẹ New Nigeria People's Party (NNPP) tí sọ nínú ọrọ rẹ fún àwọn oníròyìn wípé kòsí nkan gidi kan tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun. O ní àwọn ẹgbẹ mejeji ni wọn tí tuko iṣẹ ìjọba ìpínlè Òsun tí a sì ti rí ohùn tí wọn ṣe ati ohun ti wọn le se. Ìjọba tí o bá lè fi ebi pa awọn ọmọ ìlú rẹ o ni nkan gidi tí o le ṣe fún wọn. O wa ro gbogbo ọmọ ìpínlè Òsun láti fojú silẹ dibo fún ẹni tí yíó fún wọn ní ìgbé ayé irorun yatọ sí àwọn tí yíó fí ohunje ti o to nkan àti ẹgbẹrun kàn naira(₦1,000) tán wọn láti tún jẹ wọn mọ ayé fún ọdún mẹrin míràn.
Comments
Post a Comment