Ẹ yé kọ ohùn tí kò dára nípa orílè-èdè Nigeria mọ ẹyin o ní ìwé ìròyìn torí bí o ni gba ba ṣe pé igba rẹ na ní wọn a ṣe bá pe
Ẹ yé kọ ohùn tí kò dára nípa orílè-èdè Nigeria mọ ẹyin o ní ìwé ìròyìn torí bí o ni gba ba ṣe pé igba rẹ na ní wọn a ṣe bá pe
Kabiesi Alayeluwa Oba Hameed Adekunle Oyelude MAKAMA CON Olowu ti Owu Kuta ni wọn tí rọ àwọn oníròyìn láti maá fí gege wọn kọ ohùn búburú nípa orílè-èdè Nigeria mọ torí wípé ko ní ànfààní kánkan tí yíó ṣe fún wa o. Ninu ọrọ Oba alaye ohùn ní wọn tí ní kó sí orile-ede tí kò ní kudiẹ kudiẹ tí e sugbon ọgbọn ní wọn fi n to. Wọn ní kí àwọn oníròyìn yé tí torí owo gba abode fún orilede yí torí bí o ni gba ba ṣe pé igba rẹ na ní àwọn èèyàn yio se bá pé.
Ọrọ yi lo jẹ jáde ní igba tí oniroyin ile iṣẹ wa ni Kijipa TV n ṣe iforowero pelu Oba Aládé ohun latari àmì ẹ̀yẹ orilede yi CON ti aare ana Muhammadu Buhari fí da wọn lọla.
Oba Olowu Kuta ninu ọrọ wọn bakanna ṣe ileri láti túbọ̀ má gbaruku ti awọn ọdọ ni ilu awọn ati lorilede yi bí àwọn ti ṣe má n ṣe tẹlẹ. Kabiesi wá dupẹ lọwọ gbogbo awọn ènìyàn tó bá wọn dawọ ìdùnnú pẹlu àmì ẹ̀yẹ na pápá jùlọ àwọn ọmọ ologun orile-ede yi pẹlu ipa tí wọn kò lori gbigba ami ẹyẹ na tori awọn gan ni wọn ṣe akitiyan láti kọ ìwé sí aare ana Muhammadu Buhari pe Oba Olowu Kuta yẹ leni ti wọn n fún ni ami ẹyẹ tí orilede yi.
Comments
Post a Comment