Skip to main content

Posts

Showing posts from May, 2022

Faduri Oluwadare Joseph gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ Orile-ede Nigeria labẹ ẹgbẹ Oṣelu Labour party.

  Faduri Oluwadare Joseph tí gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ Orile-ede Nigeria labẹ ẹgbẹ Oṣelu Labour party.   Ṣe ní ìdùnnú gbà ojú gbogbo awọn èyán ní ìgbà tí oludije sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí Faduri Oluwadare Joseph tí gbogbo èyán mọ sí FADOJOE ṣe bẹ gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ Labour party. Form ohun tí oye re jẹ ọgbọn Million Naira (₦30Million) ni Faduri gba pẹlú atilẹyin àwọn ọdọ orilede yìí tí wọn ní ojú o gbudọ tí àwa ọdọ lorilede yí wipe o to ge fún àwọn olóṣèlú alajebanu tí o bikita bóyá ebi n pá omolakeji. Nínú ọrọ rẹ, FADOJOE dupẹ lọwọ gbogbo awọn Ololufẹ àti gbogbo ọmọ orilede tí wọn jẹ kí form na o jẹ gbigba. O wa ní kó sí àníàní mọ, ohùn tí ṣetan láti rí wípé orilede Nigeria bo sí ipò tó yẹ pẹlu lile awọn olóṣèlú jegudujera kúro nínú ètò ìse ìjọba tí ayé o sí de gbogbo ọmọ orilede yí lọrun bí e ba tí dibo yan ohùn gẹgẹ bí ààrẹ ní ọdún 2023. Faduri Oluwadare Joseph lo jẹ ọmọ bíbí Ipetu ijesha ní ìpínlè Osun to fi ìlú America ṣe ibùgbé. Ìfẹ tó ní sí àwọn

Osun 2022, Ko si ohùn tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun - ọmọ ọba Adeola Adeyeye.

  Osun 2022, Ko si ohùn tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun - ọmọ ọba Adeola Adeyeye. Ọmọ Ọba Hafeez Adeola Adeyeye to je alukoro ẹgbẹ New Nigeria People's Party (NNPP) tí sọ nínú ọrọ rẹ fún àwọn oníròyìn wípé kòsí nkan gidi kan tí ẹgbẹ Oṣelu APC àti PDP ní fún àwọn ọmọ ìpínlè Òsun. O ní àwọn ẹgbẹ mejeji ni wọn tí tuko iṣẹ ìjọba ìpínlè Òsun tí a sì ti rí ohùn tí wọn ṣe ati ohun ti wọn le se. Ìjọba tí o bá lè fi ebi pa awọn ọmọ ìlú rẹ o ni nkan gidi tí o le ṣe fún wọn. O wa ro gbogbo ọmọ ìpínlè Òsun láti fojú silẹ dibo fún ẹni tí yíó fún wọn ní ìgbé ayé irorun yatọ sí àwọn tí yíó fí ohunje ti o to nkan àti ẹgbẹrun kàn naira(₦1,000) tá n wọn láti tún jẹ wọn mọ ayé fún ọdún mẹrin míràn.

Ẹyin Oludibo Ipinle Osun, e má ṣe gbà rice àti owo lati dibo ní July bíbẹ ko, ìyá ọdún mẹrin mìíràn lẹ n kọ lẹta si o - Ademola Bayonle DAB

  Osun 2022 - Ẹyin Oludibo Ipinle Osun, e má ṣe gbà rice àti owo lati dibo ní July bíbẹ ko, ìyá ọdún mẹrin mìíràn lẹ n kọ lẹta si o - Ademola Bayonle DAB. Oludije fún ipo Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun labẹ àsìá ẹgbẹ YPP Dókítà Ademola Bayonle ti kesi gbogbo ọmọ ìpínlè Osun lati yago fún àwọn olóṣèlú dibo ko sebe tori wọn o ni nkankan lati se fún wọn lẹyìn idibo. DAB gẹgẹ bí àwọn ènìyàn tí n pe Oludije na sọ ọrọ yii ni ìgbà to n ba ile iṣẹ Kijipa TV sọrọ lori eto Idibo Osun 2022. O ni ki gbogbo ọmọ ìpínlè Osun o dibo yan eni to ni ifẹ wọn lọkàn tó sì ṣetan láti mú wọn kúro ninu wahala ai sí iṣẹ ati ebi ti awọn olóṣèlú ipinle Osun fí wọn sì. O ni bí àwọn ọmọ ìpínlè Osun ba fi le ta ibo wọn tori owo abi ohunje, nṣe ni won tun kọ lẹta si ìyá ọdún mẹrin mìíràn. O ni ẹgbẹ YPP nikan ní ẹgbẹ to ṣetan láti tún ìpínlè Osun ṣe.

Alaafin Oyo darapo mo awon baba nla won

  Èrin wo, Àjànàkú sun bi oke. Iku ti ku o! Arun o ri tí ọlọjọ wo o. Alayeluwa Oba Adeyemi Alaafin Oyo dara ile. Baba tí ṣe bẹ, wọn tí lọ darapọ̀ mọ awọn baba nla wọn. Kí Elédùà gba abo baba.