Faduri Oluwadare Joseph gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ Orile-ede Nigeria labẹ ẹgbẹ Oṣelu Labour party.
Faduri Oluwadare Joseph tí gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ Orile-ede Nigeria labẹ ẹgbẹ Oṣelu Labour party.
Ṣe ní ìdùnnú gbà ojú gbogbo awọn èyán ní ìgbà tí oludije sí ipò ààrẹ orílẹ̀-èdè yìí Faduri Oluwadare Joseph tí gbogbo èyán mọ sí FADOJOE ṣe bẹ gbà form láti dije fún ipò Ààrẹ labẹ àsìá ẹgbẹ Labour party. Form ohun tí oye re jẹ ọgbọn Million Naira (₦30Million) ni Faduri gba pẹlú atilẹyin àwọn ọdọ orilede yìí tí wọn ní ojú o gbudọ tí àwa ọdọ lorilede yí wipe o to ge fún àwọn olóṣèlú alajebanu tí o bikita bóyá ebi n pá omolakeji. Nínú ọrọ rẹ, FADOJOE dupẹ lọwọ gbogbo awọn Ololufẹ àti gbogbo ọmọ orilede tí wọn jẹ kí form na o jẹ gbigba. O wa ní kó sí àníàní mọ, ohùn tí ṣetan láti rí wípé orilede Nigeria bo sí ipò tó yẹ pẹlu lile awọn olóṣèlú jegudujera kúro nínú ètò ìse ìjọba tí ayé o sí de gbogbo ọmọ orilede yí lọrun bí e ba tí dibo yan ohùn gẹgẹ bí ààrẹ ní ọdún 2023. Faduri Oluwadare Joseph lo jẹ ọmọ bíbí Ipetu ijesha ní ìpínlè Osun to fi ìlú America ṣe ibùgbé. Ìfẹ tó ní sí àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè yìí ló fa ti o fí ní ohun fẹ jade láti dije fún ipò aàrẹ orilede yìí láti dẹkùn ìwà bamubamu la yo, awa o mọ bi ebi n pá ọmọ enikookan èyí tí àwọn olóṣèlú jegudujera orílẹ̀-èdè yìí n wú. O ni ko sí hun to ni ki orilede ti wa na o má da bi orilede America sugbon awọn ole, ofon, alajebanu olóṣèlú Naijiria ni o jẹ. O wa ro gbogbo ọmọ orilede yìí láti jọ fí ibo wọn gbé ohùn wọlé gẹgẹ bí aare lọdun 2023 kí wọn o yàgò fún oselu dibo ko se bẹ bibẹkọ ìyá ọdún mẹrin tabi méjọ míràn ní wọn tún n kọ lẹta si o.
Comments
Post a Comment