Ẹyin Oludibo Ipinle Osun, e má ṣe gbà rice àti owo lati dibo ní July bíbẹ ko, ìyá ọdún mẹrin mìíràn lẹ n kọ lẹta si o - Ademola Bayonle DAB
Osun 2022 - Ẹyin Oludibo Ipinle Osun, e má ṣe gbà rice àti owo lati dibo ní July bíbẹ ko, ìyá ọdún mẹrin mìíràn lẹ n kọ lẹta si o - Ademola Bayonle DAB.
Oludije fún ipo Gómìnà ìpínlẹ̀ Osun labẹ àsìá ẹgbẹ YPP Dókítà Ademola Bayonle ti kesi gbogbo ọmọ ìpínlè Osun lati yago fún àwọn olóṣèlú dibo ko sebe tori wọn o ni nkankan lati se fún wọn lẹyìn idibo.
DAB gẹgẹ bí àwọn ènìyàn tí n pe Oludije na sọ ọrọ yii ni ìgbà to n ba ile iṣẹ Kijipa TV sọrọ lori eto Idibo Osun 2022. O ni ki gbogbo ọmọ ìpínlè Osun o dibo yan eni to ni ifẹ wọn lọkàn tó sì ṣetan láti mú wọn kúro ninu wahala ai sí iṣẹ ati ebi ti awọn olóṣèlú ipinle Osun fí wọn sì.
O ni bí àwọn ọmọ ìpínlè Osun ba fi le ta ibo wọn tori owo abi ohunje, nṣe ni won tun kọ lẹta si ìyá ọdún mẹrin mìíràn.
O ni ẹgbẹ YPP nikan ní ẹgbẹ to ṣetan láti tún ìpínlè Osun ṣe.
Comments
Post a Comment